Ọ̀kan nínú àwọn ọ̀gá Ọlọpa ilẹ̀ yí DCP Bassey Ewah, ti kìlọ̀ fún àwọn ọmọ orile-ede Naijiria lọ́jọ́rú tí ó kọjá yí wípé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ yàǹda ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ alágbèéká rẹ fún Ọlọpa kankan níloro àyẹ̀wò àwọn Ọlọpa láláìsí ìwé àṣẹ ṣíṣe bẹ́ẹ̀. Arákùnrin yí ṣàlàyé wípé, bí Ọlọp...