-
1.2K Views
1 Comment
7 Likes
0 Reviews
Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé arẹ́ májà kan ò sí, àmọ́ ajà má parí ni kò dáa. Èyí gan-an ló mú kí inú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Olólùfẹ́ àwọn ònkọrin tàkasúfèé nì Paul àti Peter tí wọn jẹ́ ìbejì ọmọ ìyá kan náà tí wọn ń jẹ́ "Psquare" ó máa dùn nígbà tí Wọ́n ríwọn papọ̀ lana ọjọ́rú ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kọkànlá ọdún yí lágbo àríyá kan.
Bí ẹ ò bá gbàgbé, láti ọdún bíi márùn-ún sẹ́yìn ni aáwọ̀ tó lágbára ti wà láàrin àwọn ìlúmọ̀ọ́ká olórin tàkasúfèé náà leyi tí kò sẹ́ni tó mọ ohun kan pàtó tó fa sábàbí aáwọ̀ náà láàárín wọn.
Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ń gbé e pòòyì ẹnu kiri wípé àtìgbà tí àwọn ọmọ ìyá méjì náà ti d'oníyàwó ni àìgbọ́raẹniyé ti bẹ̀rẹ̀ sí ní í wà láàárín wọn.
Àmọ́ tó bẹ́ ẹ́ jù bẹ́ ẹ̀ lọ, àní-àní kan ò sí mọ́ wípé ìjà náà ti parí láàárín wọn báyìí nítorí ṣe ni àwọn méjèèjì bọwọ́ tí wọ́n sì tún dìmọ́raawọn lójútáyé láìpẹ́ yi.
Kódà, wọ́n ní ìyàwó Paul gan an fi fọ́nrán amóhùnmáwòrán kan síta èyí tó ṣàfihàn Peter pẹ̀lú àwọn ọmọ àwọn méjèèjì tí wọn ń ra ọjà nílé ìtajà ìgbàlódé kan.
"A gbà á ladura wípé kí Olódùmarè ó yanjú ọ̀rọ̀ náà tán pátápátá láàrín wọn kí wọn ó sì maa ṣe bí i tàtẹ̀yìnwá". Èyí ni àdúrà tí ọ̀pọ̀ àwọn Olólùfẹ́ wọn ń gbà fúnwọn
Share this page with your family and friends.