-
1.7K Views
0 Comments
2 Likes
0 Reviews
Agbẹjọ́rò àgbà nílẹ̀yí tótúnjẹ́ mínísítà ìdájọ́, Arákùnrin Abubakar Malami ti sẹ́ ẹ̀sùn kan tí wọ́n fi kàn án wípé ó lẹ́bọ lẹ́rù nípa àwọn ohun ìní tí ìjọba àpapò gbà lọ́wọ́ àwọn ènìyàn tí wọn ń tà lọ́nà àìtọ́.
Nínú àtẹ̀jáde ọ̀rọ̀ tí ẹni tójẹ̀ alukoro fún ọ̀rọ̀ ìròyìn rẹ̀ Dr. Umar Gwandu sọ, ló ti ṣe é lálàyé wípé ìròyìn tó ń dé sétíìgbọ́ àwọn ni wípé agbẹjọ́rò àgbà nílẹ̀yí jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn tó ń ta àwọn ohun ini tíjọba àpapọ̀ ilẹ̀ yí gbẹ́sẹ̀lé lọ́wọ́ àwọn aráàlú kan ní bòńkẹ́lẹ́.
Ó ṣe é lálàyé wípé, iléeṣé agbẹjọ́rò àgbà ilẹ̀ yí ò ní ǹkankan ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ náà. Ó wáá rọ àwọn ènìyàn tí wón bá mọ àwọn ọ̀bàyéjẹ́ tó ń bẹ nidi ọ̀rọ̀ náà láti ṣe àfisùn wọn nítorí kí ọwọ́ òfin ìjọba ó lè baà tówọn.
Ó ní gbogbo dúkìá ìjọba tí wọ́n ní wón ń tà yí, ní agbẹjọ́rò àgbà ilẹ̀ yí ò fọwọ́sí àtipé wọ́n ti ṣàgbékalẹ̀ ìgbìmọ̀ oluwadi kan tí ó máa tanná yẹbẹyẹbẹ láti wádìí ọ̀rọ̀ náà láàrin ọ̀sẹ̀ kan.
Share this page with your family and friends.