-
752 Views
0 Comments
2 Likes
0 Reviews
Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé ìròyìn nípa ikú òjijì tó pa akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ Dowen Sylvester Oromoni kì í ṣe tuntun mọ, àmọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn pàápàá àwọn abiamọ rere tòótọ́ ni ó wùn láti rídìí òkodoro ohun tó fa sábàbí ikú rẹ.
Lọ́sẹ̀ tó kọjá ni ìròyìn nípa ikú ọmọdékùnrin náà tànká wípé kíkùnà rẹ láti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òkùnkùn tí àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ pè é sí ló múwọn lùú bí i kíkú bí i yíyè leyi tí ó ṣe ìpalára púpò fún àgọ́ àrà rẹ. Èyí ló sì padà ṣokùnfà ikú òjijì ọmọ ọ̀hún.
Àmọ́ o, àwọn agbófinró ti fọwọ́ ọ ṣìkún òfin mú márùn-ún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wón fẹ̀sùn kàn lórí ọ̀rọ̀ yí, wọn sì ti fiwọ́n pamọ́ sí ọgbà àtúnṣe ìwà ọ̀daràn àwọn ọmọdé títí tí ìwádìí ó fi parí lórí ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú ọ̀hún. Gbogbo akitiyan yi dá lórí ìgbésẹ̀ ìjọba Ìpínlẹ̀ Èkó lójúnà àti ríi dájú pé ẹlẹ́sẹ̀ kan kì yóò lọ láìjìyà.
Kódà, àárẹ̀ Muhammad Buhari pàápàá ti ṣèlérí wípé, dandan gbọ̀n ni láti fìyà tóbátọ́ jẹ ẹnikẹ́ni tí aje ìwà ọ̀daràn náà bá ṣímọ́ lórí. Kí Olódùmarè ó sáà ma ṣe aláàbò lórí kálukú wa.
Share this page with your family and friends.