Ọwọ́ titẹ ògbólógbò ọkùnrin ajínigbé kan tóti ń dàwọn èèyàn láàmú ni Ìpínlẹ̀ Èkìtì àtì Òndó.
Arákùnrin ògbólógbòó ajínigbé kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bùnmi Ògúnrẹ̀mí ẹni ọdún mọ́kàdínláàdọ́ta lọ́wọ́ àwọn Ọlọpa titẹ báyìí ni ìpínlè Ekiti. Arákùnrin yí nìròyìn fìdí rẹ múlè wípé ó fẹnu araarẹ̀ jẹ́wọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣé ìjínigbé tóti ṣe. Kódà, ìyá ìyàwó rẹ̀ wà lára àwọn tóti jí gbé rí.
Arákùnrin yí tí ìnagijẹ rẹ ń jẹ́ Bùnmi Bafon jẹ́ ọmọ bíbí Àdó-Èkìtì. Òun pẹ̀lú ẹni tí ó sì jẹ́ agbódegbà rẹ tí ó máa ń báwọn ṣètò oúnjẹ fáwọn tí wọn bá jígbé náà ni ọwọ́ jọ tẹ̀. Iṣẹ́ fọganáísà ni òun ń ṣe.
Lákòókò ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn yí, niwọ́n ti dárúkọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn tí wọn ti lùgbàdè wọn. Lára wọn ni arákùnrin oníṣòwò epo rọ̀bì bẹntiroolu kan ni Ureje, Ado-Ekiti, tórúkọ rẹ ń jẹ Alhaji Sulaimon Akinbamì. Wọ́n tẹ̀ síwájú nínú ìjẹ́wọ́ náà wípé àìmọye ni iṣẹ́ ìjínigbé tí àwọn tún ti ṣe ní Ìpínlẹ̀ Èkìtì àti Ondo.
Arákùnrin Ògúnrẹ̀mí ajínigbé yi sọ gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ lédè Yoruba lákòókò ìjẹ́wọ́ náà, ó sì tún sọọ́ di mímọ̀ wípé ìyá ìyàwó òun gan an wà nínú àwọn tí òun ti jígbé rí.
Nkan ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé yí, àfi kí Olódùmarè ó máa ṣamọ̀nà kóówá wa ni.