-
1.4K Views
0 Comments
1 Like
0 Reviews
Látàrí ojú ìwòye tí gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní Ìpínlẹ̀ Imo Rochas Okorocha fi ń wo bí ohun gbogbo tí ń lọ nílẹ̀ yí, pàápàá ìrúnú àwọn ọ̀dọ́ nípa ìṣàkóso ìjọba orílẹ̀ èdè yí, ló mú u tètè ké sí àwọn ọ̀dọ́ orílẹ̀-èdè yí pẹ̀lú ẹkún wípé kí wọn ó má fi ìkanra mọ́ àwọn aláìṣẹ̀ gbogbo bíi àwọn olórí ìlú látàrí ìkùnà ìjọba ilẹ̀ yí.
Okorocha sọ̀rọ̀ yí lọ́jọ́rú tí ó kọjá yí ni Eziama Obierie, nijoba ìbílẹ̀ Nkwerre nipinle Imo níbi ayẹyẹ ètò ìsìnkú ìyá ọkọ ọmọ rẹ Jemaimah Nwosu, lójú ọkọ ọmọ rẹ Uche Nwosu ló ti fomijé ojú sọ̀rọ̀ wípé Ìpínlẹ̀ Imo ń ṣòjòjò látàrí àìsí ètò ààbò tó péye. Ó wáá ní dípò kí àwọn ọ̀dọ́ ó máa dàlúrú tàbí ṣèkọlù sí àwọn olórí ìlú nítorí ipò tí Ìpínlẹ̀ ọ̀hún wà lórí ètò ààbò yí, ó sán kí wọn ó ní sùúrù di ọdún 2023 tí wọ́n máa láǹfààní láti dìbò yọ ẹnikẹ́ni tí kò ṣèjọba dáadáa dànù nípasẹ̀ ètò ìdìbò tó múnádóko.
Bí ó ti ṣe ń sọ̀rọ̀ yí ló ń sunkún pẹ̀lú fífi ẹ̀dùn ọkàn béèrè wípé ṣé kì í ṣe Ìpínlẹ̀ tí àwọn darí rẹ rèé ni fọ́dún mẹ́jọ kótóódipé àwọn gbé ìṣàkóso rẹ kalẹ̀ lọ́dún 2019. Ó tẹ̀ síwájú pé gómìnà bíi mẹ́fà tó ń bẹ lórí àlééfà lọ́wọ́ báyìí ni kò báwá síbi ètò ìsìnkú náà, àmọ́ tó jẹ́ pé àìsí ètò ààbò tó péye yí ló múwọn fìdí mọ́lé wọn.
Okorocha wáá ni òun rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí àwọn ọ̀dọ́ ìlú náà wípé kí wọn o dákun jọ̀wọ́ má hùwà ìkọlù sí àwọn aláìṣẹ̀ mọ látàrí ìfẹ̀hónú ẹni hàn síjọba nípa Ìwà kòtẹ́nilọ́rùn tí ìjọba ń hù síwọn. Ó ní kì í ṣe Ìpínlẹ̀ Imo tí òun mọ tẹ́lẹ̀ nìyẹn.
Okorocha tesiwaju nínú ọ̀rọ̀ rẹ wípé, òun ò ní faramọ́ rògbòdìyàn rárá lábẹ́ ẹ bíítí wulẹ̀ ọ́ mọ àmọ́ òun ó lùlù àtìlẹ́yìn fún ẹnikẹ́ni tó bá fi èhónú rẹ̀ hàn lọ́nà tí ó bá òfin mu. O ní nítorí náà, òun ó ròwọ́n kí wọ́n ní sùúrù di ọdún 2023 tí wọ́n máa ní àǹfààní láti lo káàdì ìdìbò alálòpẹ́ láti fi ìbò yọ olùṣèjọba tí kò dára dànù.
Share this page with your family and friends.