-
1.2K Views
0 Comments
0 Likes
0 Reviews
Èròńgbà gbogbo ènìyàn lásìkò ọdún kọ̀ọ̀kan ni pé, bí ọdún bá ti ń lọ sópin bí èyí kí Olódùmarè o máa fìṣọ́ rẹ̀ ṣọ́ni nítorí àtilè rọ́dún tuntun. Ọ̀pọ̀ ló sì tún máa ń wùn láti rìnrìn àjò lọ sí ìlú wọn lójúnà àtirí àwọn mọ̀lẹ́bí wọn tí wọ́n ti rí tipẹ́ pàápàá àwọn ènìyàn gbogbo tó fi ìlú Èkó ṣ'àtìpó.
Irúfẹ́ ìrìn àjò báyìí ni arábìnrin yí àti àwọn ọmọ rẹ obìnrin méjì rìn lọ́jọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù yí láti Ìpínlẹ̀ Èkó lọ sí apá ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè yí, tósìjẹ́pé ojú ọ̀nà márosẹ̀ niwọ́n parí ìrìnàjò ayé wọn sí.
Gẹ́gẹ́bí àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ jàm̀bá ọkọ̀ náà ṣojú rẹ ṣe sọ, wọ́n ní eré àsápajúdé ni awakọ̀ náà ń sá, pẹ̀lú bí ó sì ti ń gbìyànjú láti ya ọkọ̀ tíḿbẹ lẹgbẹ rẹ̀ sílẹ̀, sàdéédé ló rálu ọkọ̀ Àjàgbé kan tí wọ́n wà gúnlẹ̀ sí ẹ̀bá ọ̀nà tó sì larí mọ́ọ lójiijì lójú ọ̀nà Sagamu.
Wọ́n ní láláìsí àní-àní, ojúẹsẹ̀ ni obìnrin tí dẹ́rẹ́bà ń gbé rìnrìn àjò àtàwọn ọmọbìnrin rẹ méjèèjì dolóògbé tósìjẹ́pé kiní kan báyìí ò ṣe awakọ̀ ọ̀un.
Ìròyìn fìdí rẹ múlè wípé, ìlú òyìnbó ni ọkọ arábìnrin náà n gbé.
Àfi k'Élédùmarè ó máa fìṣọ́ rẹ̀ ṣọ́wa kámá rìnrìn àjò àlọ àìdé.
Share this page with your family and friends.