-
1K Views
1 Comment
2 Likes
0 Reviews
Ìròyìn yàjó-yàjó.
Ìyàwó Ọṣìbọ́nà, ọkùnrin tó nilé alájà mọ́kànlélógún tó dà wó ní Ìkòyí l'Eko ti ń jà sáwọn dúkìá ọkùnrin náà pẹ̀lú àwọn mọ̀lẹ́bí olóògbé.
Ọkọ̀, owó báńkì, àti àwọn dúkìá olówó iyebíye míràn niwọ́n ń jà sí,
Lọ̀rọ̀ bá dọ̀rọ̀ agbẹjọ́rò.
Àwọn ìbátan arákùnrin Ọṣìbọ́nà tó nilé alájà mọ́kànlélógún tó dà wó lágbègbè Ìkòyí Èkó ti bẹ̀rẹ̀ sí níí báraawọn jàjàkúakátá báyìí lórí dúkìá ọkùnrin olóògbé náà.
Ìròyìn táagbọ́ láti ẹnu ẹnìkan tó súnmọ́ mọ̀lẹ́bí náà fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé ní kété tí ìyàwó arákùnrin olóògbé náà dé láti òkè òkun lórílẹ̀ èdè United States of America tó ń gbé sí ilé ọkọ rẹ̀ tówàní ojúnà Mosley Ìkòyí ni àwọn ìbátan olóògbé náà ò ti gbàá láàyè láti wọnú ilé ọ̀hún.
Ìròyìn fi ń yéwa wípé Abílékọ Ọṣìbọ́nà ìyá ọlọ́mọ mẹrin ọ̀hún ti gbé pẹ́rẹ́gi kaná pẹ̀lú àwọn ìbátan ọkọ rẹ yí tí wọn ò fẹ́ fààyè gbàá láti ní ìpín kankan nínú ogún ọkọ rẹ̀.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó tó ń bẹ ní báńkì, àwọn ọkọ̀ aláfẹ́ bọ̀gìnì-bọ̀gìnì, àti àwọn dúkìá olówò iyebíye míràn ni ohun tí wọn ń jà sí.
Àwọn mọ̀lẹ́bí arákùnrin yí niwọ́n ní wọn ò ti ẹ̀ fún ìyàwó rẹ̀ láàyè rárá láti wọnú 'yàrá arákùnrin náà rárá nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó àti àwọn kọ́kọ́rọ́ ọkọ̀ gbogbo tó wà níbẹ̀.
Ẹni ọ̀rọ̀ ṣojú rẹ̀ sọ wípé igun méjì mọ̀lẹ́bí olóògbé yí niwọ́n wá sílé rẹ̀ pẹ̀lú àwọn olọ́pàá kogberegbe(Mobile Police, MOPOL) tó sì jẹ́ pé àbálọ àbábọ̀ ohun gbogbo, ṣeni àwọn alabagbele ọkùnrin olóògbé náà ti gbogbo wọn síta nítorí rúgúdù tí ó wà láàárín wọn.
Ẹnìkan tí ó wà níbi ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún sọ wípé
"Àwọn ìbátan Ọṣìbọ́nà àti ìyàwó rẹ̀ ń báraawọn jà nítorí ogún rẹ láláìtí jẹ́ pé wọ́n sin òkú rẹ̀. Tòhun ti wípé arábìnrin náà bímọ mẹrin fún olóògbé nìyẹn o. Wọ́n wá ń báraawọn jà nítorí ogún. Kódà, ìyàwó rẹ̀ wá sí ibi ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú ohun, tí ó sì ń pariwo lé àwọn ìbátan ọkọ rẹ̀ wípé Wọ́n fẹ́ tojú òun yan òun m'ẹ́bọ. Ó ní láti jẹ́ pé owó rẹpẹtẹ wà nínú ilé náà "
" Àwọn àbúrò Femi níláti dá ìyàwó àti ọmọbìnrin rẹ̀ dúró láti ma wọlé sínú 'yàrá náà. Ó jẹ́ ohun ìjọlójú gbáà láti rírú ìṣẹ̀lẹ̀ yí, àti pé owó ni gbòǹgbò ẹ̀ṣẹ̀.
Àwọn ìbátan rẹ sọ fún un wípé kí ó lọ sílé ìtura, àmọ́ ó ní kò sówó lọ́wọ́ òun láti ṣe bẹ́ẹ̀"
Ẹnìkan náà tí ọ̀rọ̀ ohun ṣojú rẹ tún ṣàlàyé wípé,
" Ìyàwó olóògbé wálé pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olọ́pàá kogberegbe, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn mọ̀lẹ́bí olóògbé ṣe. Èyí gan-an ló mú kí olúkúlùkù wọn ó máa pariwo léraawọn lórí tí wọn ò sì jẹ́ kí àlàáfíà ó jọba. Wọ́n fẹ́ẹ̀ ẹ́ tó ogún, ó sì ti ń lọ bí i aago méjìlá òru, èyí ló mú wa lé gbogbo wọn dà síta nítorí kò sẹ́ni tó fẹ́ẹ́ gbà fúnraawọn. Ìta gbangba yí niwọ́n wà tí ilẹ̀ fi mọ́. Bí oníwà ti ń ṣépè ni ẹléyìn ń kanrímọ́nú, tí ìdúnkookò mọ́raaẹni sì ń lọ láàárín wọn dípò kí wọn ó máa ṣọ̀fọ̀ arákùnrin ọ̀hún, wàhálà lórí ogún rẹ̀ ni wọ́n ń báraawọn fà"
"Kódà, wọ́n ti gbéṣẹ́ fún agbẹjọ́rò àgbà Olisa Agbakoba ṣe nítorí ọ̀rọ̀ yí"
Share this page with your family and friends.