-
790 Views
0 Comments
2 Likes
0 Reviews
Kaabiesi Aláyélúwà Ọba Làmídì Adéyẹmí III ti fa àwọn akẹ́kọ̀ọ́ méjì tí àwọn ajínigbé jígbé ní agbègbè Àgbàdo crossing ni Ìpínlẹ̀ Ògùn lé àwọn òbí wọn lọ́wọ́.
Nígbà tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga girama náà ń ṣàlàyé bí wọn ṣe báraawọn n'ilu Ọ̀yọ́ àti ohun tí ojú wọn rí lọ́wọ́ àwọn ajínigbé náà, jẹ́ ǹkan ìkàyà àti ìyàlẹ́nu ńlá gbáà fún àwọn ènìyàn tí ó wà níbẹ̀.
Àwọn ọmọdébìnrin méjèèjì Zainab Rafiu, ọmọ Ọdún méjìdínlógún(18) àti Kẹ́hìndé Adéògún tí wọn jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ Ọdéwálé Community High School ni Àgbàdo Crossing, Ojúurin, Ìpínlẹ̀ Ògùn làwọn ajínigbé yí jígbé lọ́jọ́ Etì tí ó kọjá yí.
Àwọn ọmọdébìnrin méjèèjì ṣàlàyé pé, lákòókò tí àwọn ń relé ẹ̀kọ́ àwọn lowurọ ọjọ́ náà, ṣàdéédé ni ọkọ̀ kan tí àwọn ọkùnrin mẹ́ta wà nínú rẹ̀ dúró lójijì sí ẹ̀gbẹ́ àwọn tí wọ́n sì ṣílẹ̀kùn wípé kí àwọn ó wọlé sínú rẹ̀ lójú ìbọn. Ohun ìyàlẹ́nu ibẹ̀ nipé, àwọn ọmọdébìnrin yín láwọn ò mọ bí àwọn ṣe bàraàwọn nílùú Ọ̀yọ́ lẹ́yìn tí àwọn wọnú ọkọ̀ náà tán.
Nígbà tí àwọn ajínigbé yí gbé àwọn ọmọdébìnrin náà dénú igbó ńlá kan, wọ́n dẹ̀wọ́n mọ́gi lọ́tọ̀ọ̀tọ̀, wọ́n sì bá tiwọn lọ. Wọn fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé èdè Yorùbá pọ́ńbélé ni àwọn ajínigbé náà ń sọ jáde lẹ́nu. Wọn ní, ọ̀kan nínú wọn ti ẹ̀ sọ wípé:"Ayé yín máa tóó wá sopin nínú igbó yí" síwájú kí wọn ó tó ó fi wọ́n sílẹ̀ sórí ìso.
Kẹ́hìndé, ọkàn nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yi ló jà raburabu láti fi eyín rẹ̀ já okùn tí wọ́n fi soó, kó tó ó di pé ó tú èkejì rẹ̀ náà sílẹ̀
Láláìjáfara, wọn sá kúrò ní agbègbè náà láláì ti ẹ̀ jẹ́ pé wọ́n mọ ibi tí wọ́n lè lọ fún bí i wákàtí méjì nínú igbó yí kó tóó di wípé wọn jásí ojú ọ̀nà márosẹ̀ kan tí wọn ò mọ̀. Ìgbà tí wọ́n béèrè ibi tí wón jásí yí, ni wọ́n tóómọ̀ wípé ojúnà márosẹ̀ kan n'ilu Ọ̀yọ́ ni.
Bí Kẹ́hìndé ti gbọ́ pé ìlú Ọ̀yọ́ làwọn wà, òòye kan sọ síi lọ́kàn láti wá ọ̀nà dé agboolé wọn nítorí pé ọmọ ìlú Ọ̀yọ́ lòun ń ṣe. Àmọ́ ọmọ náà kò mọ bí yóò ti ṣe débẹ̀ láti ibi tí wọ́n wà yí. Wọ́n rí ìyá olóúnjẹ kan, wọn ṣàlàyé gbogbo bí ìrìnàjò wọn ti rí fún un, wọ́n bẹ̀ ẹ́ kí ó yáwọn ní ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ rẹ, èyí tí Kẹ́hìndé lò láti pe àwọn òbí rẹ ni Abẹ́òkúta láti lè jẹ́ kí wón ó mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ àti ibi tí wón wà lákòókò náà.
Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni Bàbá Kẹ́hìndé ti fi nọ́mbà ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ kan n'ilu Ọ̀yọ́ tí wọ́n lè pè ráńṣẹ́, kò sì pẹ́ sí àsìkò náà rárá tí Alhaji Ògúnṣọlá tí wọ́n pè fi dé síbẹ̀ tí ó sì kó àwọn ọmọdébìnrin náà lọ sí ààfin ikú bàbá yèyé, káábíèsí ọba Adéyẹmí Aláàfin Ọ̀yọ́. Tí wọ́n sì ṣàlàyé gbogbo bí ọ̀rọ̀ ohun ti jẹ́.
Lójúẹsẹ̀ ni Aláàfin ti fọ̀rọ̀ náà tó àwọn ẹ̀ṣọ́ àjọ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ létí, wọ́n sì ṣẹ̀tọ́jú àwọn ọmọ náà dáadáa nípa fífúnwọn lóúnjẹ, ààyè tí wọ́n ti f'ára nisinmi àti ṣíṣe ìtọ́jú wọn ní'lànà ìṣègùn òyìnbó nítorí kí ìrírí burúkú ti wọn ni yi má baa lapa òdì láraawọn.
Àwọn ọmọdébìnrin náà tún ṣàlàyé lọkọ̀ọ̀kan fún àwọn ikọ̀ akọ̀ròyìn Aláàfin ohun tí ojú wọn rí lákàtà àwọn ajínigbé tí wọ́n jẹ́ afiniṣowó tàbí ìráńṣẹ́ èṣù ọ̀hún.
Lákòókò tí wọn ń kó ìròyìn yí jọ, àbúrò bàbá Kẹ́hìndé, Kazeem Wasiu ti dé sí ààfin Ọ̀yọ́ bayi láti Àgbàdo crossing Ojúurin Ìpínlẹ̀ Ogun láti mú Kẹ́hìndé Adéògún àti ọrẹ rẹ tí wọn jọ jígbé ní ikọwọ rìn pẹ̀lú bàbá àgbà kan, Pa Samuel Adebanjo Adéògún, ẹni ọdún méjìdínlọ́gọ́rin. À fi kí Olódùmarè ó máa ṣọ́wa lọ́jọ́ gbogbo kí orí wa ó sì má gbàbọ̀dẹ̀.
Share this page with your family and friends.