-
1.1K Views
0 Comments
4 Likes
0 Reviews
Ọ̀kan nínú àwọn ọ̀gá Ọlọpa ilẹ̀ yí DCP Bassey Ewah, ti kìlọ̀ fún àwọn ọmọ orile-ede Naijiria lọ́jọ́rú tí ó kọjá yí wípé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ yàǹda ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ alágbèéká rẹ fún Ọlọpa kankan níloro àyẹ̀wò àwọn Ọlọpa láláìsí ìwé àṣẹ ṣíṣe bẹ́ẹ̀.
Arákùnrin yí ṣàlàyé wípé, bí Ọlọpa bá ń ṣíṣe ìwádìí, dandan ni fúnwọn láti pèsè ìwé àṣẹ iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ síwájú u kí wọn ó tó bèèrè fún yíyẹ ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ ẹni wò.
Arákùnrin Ewah yànnàná ọ̀rọ̀ yi níbi ètò kan tí ìgbìmò àwọn aráàlú àti ibasepo àwọn olopa sagbekale rẹ nipinle Èkó laipe yí. Nígbà tí ó ń dáhùn sí àwọn ìbéèrè gbogbo tí wọ́n ń bi í.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ, ó ní :
"Mo sọ́ mo tún ń tún un sọ, wípé kí ẹnikẹ́ni ó má ṣe yàǹda ẹ̀rọ ibanisoro rẹ fún agbofinro kankan lérònà nítorí kò sí nínú àlàálẹ̀ wa. Ti a ba ń ṣíṣe ìwádìí tí ó jọ mọ́ ǹkan bẹ́ẹ̀, dandan ni fúnwa láti pèsè ìwé àṣẹ ṣíṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, kí olúkúlùkù wa ó fi èyí sọ́kàn.
Ọ̀gá Ọlọpa náà tún sọ̀rọ̀ lórí akitiyan ìjọba àpapọ̀ látàrí fífì òpin sí igbalaaye àwọn ọkọ̀ tí àwọn gíláàsì wọn máa ń dúdú batakun ti wọn ń kó wọ̀lú láti rí i wípé àwọn agbofinro ń ṣàyẹ̀wò irúfẹ́ ọkọ̀ bẹẹ.
Arákùnrin Ewah ṣàlàyé pé "Ẹ wí fún àwọn ènìyàn yín gbogbo tàbí àwọn ọrẹ yín lójú pópó pé tí ẹ bá ti fi àwọn ìwé ọkọ̀ yín han Ọlọpa, tí Ọlọpa náà bání kò tẹ́ òun lọrun, ẹ má wulẹ̀ baa jiyàn rárá, ẹ ṣáà sọ fún un wípé kí ó jé kí ẹ jọ máa lọ sọ́dọ̀ ọ̀gá Ọlọpa tó ń ṣàbójútó àgbègbè náà"
Lọ́dún 2019, àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àwọn agbofinro nílẹ̀ yí ti yànnàná àwọn ìlànà kan tí kò níí máa jẹ́ kí àwọn aráàlú máa ní gbọ́nmisi-omiòto pẹ̀lú àwọn agbofinro Ọlọpa làwọn ibùdó ayẹwo wọn.
Àwọn àlàálẹ̀ wọ̀nyí wáyé lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀sùn látọ̀dọ̀ àwọn aráàlú lórí ìpakúpa àti ìṣeniléṣe tí ó ń wáyé látọ̀dọ̀ àwọn Ọlọpa sí aráàlú.
Àwọn agbofinro Ọlọpa ṣe ìfiléde yí sórí àwọn ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ ẹ̀rọ alátagba ti twitter wọn @policeNG lóṣù karùn-ún ọdún yí, wón sì tún rọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ orílẹ̀ èdè yí láti má maa jiyàn tí kò nidi pẹ̀lú u èyíkéyìí òṣìṣẹ́ ìjọba tí ó gbebọn dání lẹ́nu iṣẹ́.
Wọ́n tún wáá mú ìmọ̀ràn wá wípé kí ẹnikẹ́ni ó má maa fi àìdunnú kankan hàn nígbàkigbà tí Ọlọpa bá dáwọn dúró láti ṣíṣe ẹ wọn.
Share this page with your family and friends.