Iléeṣé Ọlọpa tìlú Àbújá ti kéde rẹ̀ wípé wọ́n ti ṣàwárí akòròyin Iléeṣé ìwé ìròyìn Vanguard, Henry Salem Tordue, tí wọ́n ti ń wá lọ́jọ́ díè sẹ́yìn. Àmọ́ ipò òkú ni Wọ́n bá arákùnrin nítorí wọn ní awakọ̀ kan ló pa á lágbègbè Manushi lojuna marose timbe n'ilu Àbújá.
Afurasí òun, ẹni ọdún mọ́kàdínlọ́gbọ̀n tí ó jẹ́ awakọ̀ èrò tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Itoro Clement ni wọ́n fojú rẹ̀ hàn lọ́jọ́ Ẹtì tó kọjá yí nílùú Abuja.
Nígbà tí eni tí ó jẹ́ alukoro àwọn Ọlọpa nílẹ̀yí Frank Mba ń ṣàfihàn rẹ, lo ti se é lálàyé wípé arákùnrin náà wa ọkọ̀ ọ Toyota Camry tí nọ́mbà ìdámọ̀ rẹ̀ jẹ́ BWR 243 BK lọ́jọ́ tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹ̀, àtipé ikọ̀ Olùwádìí afọngbọ́ńnú ṣiṣẹ́ lábẹ́ ìṣàkóso Gííwá Iléeṣé Ọlọpa nílẹ̀yí tí arákùnrin Olátúnjí Dìísù ṣíwájú ẹ ni wọ́n tọpinpin òkú arákùnrin yí délé ìgbóòkú pamọ́ sí kan tí ó wà níléèwòsàn àpapọ̀ tí ń bẹ Wuse tí àwọn mọ̀lẹ́bí rè sì ṣe ìdámọ̀ rẹ̀.
Káàdì ìdánimọ̀ mẹta tí ó jé ti ilé ìgbìmò asofin ilẹ̀ wá, ti ẹgbẹ́ àwọn oniroyin àti tileese ìwé ìròyìn Vanguard ní wón bá lára rẹ.
Nígbà tí dẹ́rẹ́bà tí ó fi ọkọ̀ pa arákùnrin náà ń ṣàlàyé araare fún àwọn oniroyin akẹgbẹ́ arákùnrin olóògbé náà, ni ó ti ṣàlàyé wípé òun sá kúrò ní agbègbè tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti ṣẹ̀ lọ́jọ́ náà nítorí àwọn janduku kan ti ṣe ìkọlù sì òun níbẹ̀ rí.