-
1.2K Views
0 Comments
2 Likes
0 Reviews
Ohun ìjọlójú gbáà ló jẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn nígbà tí arákùnrin kàn Festus James ń kà bòrò-bòrò níwájú àwọn agbófinró àti àwọn oníròyìn láìpẹ́ yí ni ìpínlẹ̀ Ondo.
Arákùnrin ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́ta (56) ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run ni ó hùwà kàyééfì kan ní abúlé Agbabu nítòsí Ọ̀rẹ̀ níjọba ìbílẹ̀ Odigbo ipinle Ondo nípa fífipá bá arábìnrin aláboyún oṣù mẹ́jọ kan láṣepọ̀.
Arákùnrin yí jẹ́wọ́ ìwà búburú náà nígbà tí agbenuso Ọlọpa ti Ìpínlẹ̀ Ondo DSP Funmilayo Odunlami sàfihàn rẹ pẹ̀lú àwọn ọ̀daràn mẹ́fà miran.
Gégé bí ohun tí ó sọ, ó lọ ṣe ìsọjí ọlọ́jọ́ mẹ́ta ni abúlé náà ni. Àtipé, ọjọ́ kejì ìsọjí náà ni ó sọ wípé àwọn òbí kan mú ọmọbìnrin wọn kan wá fún iṣẹ́ ìṣẹ́gun.
O ṣàlàyé síwájú sí i wípé, òun ní kí wọn ó mú ọmọbìnrin náà lọ sódò fún àwẹ̀nù ọwọ́kọ́wọ́ tí ó lè wà lára rẹ.
Ó ní, lẹ́yìn ìgbà náà loun kàn ṣàdéédé rí ọmọbìnrin náà tí ó wá bá òun nílé tí ọ̀kan nínú àwọn ará abúlé náà fún òun láti gbé fún àkókò ìsọjí ọ̀hún tí ó sì jẹ́ pé àwọn jọ ní àjọṣepọ̀ tí kò yé òun bí ó ṣe wáyé rárá. Ó ní kódà, ẹkún ni òun bú sí lẹ́yìn ìbálòpọ̀ náà nítorí ó yá òun lẹ́nu gidigidi.
Arákùnrin òun tilẹ̀ ni lóòótọ́ ni òun bá ọmọbìnrin ẹni ọdún méjìlélógún ọ̀hún láṣepọ̀, àmọ́ kì í ṣe pé òun fi tipátipá ṣe é. Àtipé èṣù ló fẹ́ ẹ́ ṣẹlẹ́yà òun.
Àmọ́ àwọn Ọlọpa ṣàlàyé wípé ọwọ́ àwọn tẹ arákùnrin yí lọ́jọ́ kẹtàlá oṣù kọkànlá ọdún yí nígbà tí wọ́n gbó nípa ìṣẹ̀lẹ̀ ohun.
Wọ́n wáá rọ àwọn ènìyàn wípé kí wọ́n ó máa wà ní ìwà a ojú lalákàn fi ń ṣọ́rí layika wọn lọ́jọ́ gbogbo. Wọ́n sì ní wón máa gbé arákùnrin náà lọ sílé ẹjọ́ ní kété tí ìwádìí bá parí lórí rẹ.
Share this page with your family and friends.