-
1.1K Views
0 Comments
1 Like
0 Reviews
Pẹ̀lú pé kò tí ì ju bí i wákàtí mẹẹdọgbọn lọ tí ìṣẹ̀lẹ̀ iná ṣúyọ ni ilé ìdalẹ̀nù kan tí ìjọba ò fọwọ́ sí ní agbègbè Rumukoro ní ìjọba ìbílẹ̀ Obio/Akpor nipinle Rivers, ìṣẹ̀lẹ̀ iná kan tún ti n ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ bayi ni agbègbè Nembe/Bonny/Jetty n'ilu Port Harcourt.
Ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàmbá iná ohun la gbọ́ pé ó ṣì ń fẹjú kẹ ẹ lọ́wọ́ níbití wọn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn òǹṣòwò káràkátà ti fara kááṣá rẹ̀ nítorí ọkọ̀ ojú-omi bíi mẹ́fà tí wọn wọ̀ ni ìjàm̀bá iná náà kọlù.
Ẹni tí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún ṣojú rẹ ṣe é lálàyé pé, lákòókò tí àwọn òǹṣòwò káràkátà ọ̀hún ń já ẹrù kúrò nínú ọkọ̀ ojú omi ọ̀hún ni ìjàm̀bá iná náà bẹ́ sílẹ̀ nítorí Wọ́n fura pé ó ṣẹéṣe kó jẹ́ pé, wọ́n gbé àwọn epo rọ̀bì sínú ọkọ̀ ojú-omi ọ̀hún lọ́nà àìtọ́.
Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìròyìn ń bọ̀ láìpẹ́......
Share this page with your family and friends.