To continue using the site you need to read the revised version and agree to the policies
-
2.2K Views 0 Comments 2 Likes 0 Reviews
Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti dá olùkọ́ mẹta dúró bayi látàrí ẹ̀sùn ìbánilòpọ̀ lọ́nà àìtọ́ tí wọ́n fi kàn wọn nílé ẹ̀kọ́ Basic School, to wà n'ilu Ògbómọ̀ṣọ́, nipinle Ọ̀yọ́. Àtẹ̀jáde yí wáyé latenu ẹni tí ó jẹ́ kọmíṣọ́nà fún ètò ẹ̀kọ́, ìmọ̀ Sayennsi àti ìmọ̀ ìgbàlódé, Arákùnrin Rahman Abdul Raheem lọ́jọ́ ẹtì tó kọjá yí, ló ti ṣe é lálàyé wípé ẹni tí ó jẹ́ gíwá ilé ẹ̀kọ́ fún àwọn onípèníjà ojú ọ̀hún ni wọ́n ti fún ní ìṣípò padà kúrò ní ilé ẹ̀kọ́ náà àti ẹni tí ó jẹ́ olórí àwọn Olùkọ́ni níbẹ̀.
Kọmíṣọ́nà ṣàlàyé wípé ìdádúró àti ìṣípò padà lẹ́nu iṣẹ́ tí wọ́n ṣe fún àwọn ènìyàn náà pọndandan nítorí àtilè fòpinsí awuyewuye tóńlọ nílé ẹ̀kọ́ náà látàrí fọ́nrán amóhùnmáwòrán kan tóńlọ káàkiri ilé ẹ̀kọ́ ọ̀hún, àti pé láti lè fi ojúṣe ìjọba hàn sírúfẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀.
Ó ṣàlàyé wípé ìgbésẹ̀ ìjọba yí o fún àwọn ìgbìmọ̀ oluwadi ẹlẹ́nimẹ́rin láàyè láti ṣe iṣẹ́ wọn bótitọ́ àti bótiyẹ láláìsí ojúùṣájú kankan Kọmíṣọ́nà tún wáá tẹpẹlẹ mọ́ọ wípé àwọn lẹ́tà ìṣípò padà àti ti ìdádúró lẹ́nu isẹ tí wọn fún àwọn ènìyàn náà ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ ní kíákíá tí ìwé náà tó àwọn ènìyàn náà lọ́wọ́ nítorí kí àlàáfíà ó lè padà sínú ilé ẹ̀kọ́ ọ̀hún
Afrosky, a vibrant social media platform dedicated to connecting people of African descent worldwide. We provide a space for users to share their experiences, connect with like-minded individuals, and celebrate African culture and heritage.
We strive to foster a supportive and inclusive community where users feel empowered to express themselves authentically.