-
1.1K Views
0 Comments
1 Like
0 Reviews
YÀJÓ-YÀJÓ :ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ APC PÍNSÍ MÉJÌ,IGUN KAN GBÉNÁWOJUÀÀRẸ BUHARI,WỌ́N YỌ BUNI KÚRÒ NÍPÒ, WỌ́N KÉDE AUDU GẸ́GẸ́BÍ ALÁGA.

Awuyewuye inú ẹgbẹ́ òsèlú APC ti gbọ̀nà àrà òmíràn yọ látàrí bíi àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú náà ti pínraawa sígun méji bayi. Kódà níbi tí rògbòdìyàn ọ̀hún le dé, ọ̀kan lára igun ọ̀hún ti yọ Mai Mala Buni dànù kúrò nípò tí wọ́n yàn án sí.
Kódà igun ọ̀hún fẹ̀sùn tó lágbára kan Ààrẹ Muhammad Buhari lórí bí ó tiṣe ń ṣàkóso ẹgbẹ́ ọ̀hún.
Bí ẹ ò bá gbàgbé wípé Gómìnà Ìpínlẹ̀ Yobe tí í ṣe Mai Mala Buni ni alaga gbogbogbò ìgbìmọ̀ alábòójútó àti ṣíṣètò ìpàgọ́ ńlá àrà ọ̀tọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú APC, àmọ́ ṣàdéédé ni èka kan láàárín ẹgbẹ́ òṣèlú náà tí a mọ̀ sí Progressive Youth Movement kéde rẹ̀ Lọ́jọ́ Ajé yí wípé àwọn ti rọ Buni lóye tí a mọ̀ọ́mọ́, tí wọ́n sì kéde Mustapha Audu lẹ́kẹ̀kẹsẹ̀ gẹ́gẹ́bí alága gbogbogbò ìgbìmọ̀ alábòójútó àti ṣíṣètò ìpàgọ́ ńlá àrà ọ̀tọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú APC láti fi rọ́pò Buni. Kódà, Wọ́n ni lọ́gán bẹ́ẹ̀ ni àṣẹ àti agbára ti dọ́wọ́ rẹ̀.
Audu, ẹni àṣẹ̀ṣẹ̀ yàn ọ̀hún nínú ọ̀rọ̀ tiẹ̀ sọ wípé, ìgbìmọ̀ olùpẹ̀tù sááwọ̀ kan máa tó wà tí yóò parí ááwọ̀ láàárín àwọn ọmọ ẹgbẹ́ gbogbo tínú ń bí síwájú Ọjọ́ Kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù kejì ọdún 2022 tí ìpàgọ́ ńlá ẹgbẹ́ òṣèlú náà fẹ́ẹ́ wáyé.
O tún kéde ìlànà ìpínsísòrí àwọn ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣẹ́ tuntun ẹgbẹ́ òsèlú náà (NWC)
Àmọ́ ẹni tí ó jé akọ̀wé àgbà lápapọ̀ fún ẹgbẹ́ òṣèlú náà John Akpan Udoedehe fajúro sí ìwà tí igun yi hu, ó sì tún ní ìwà olùdalẹ̀ ẹgbẹ́ gbáà làwọn ẹ̀ka ọ̀hún nínú ẹgbẹ́ náà hù.
Ó ṣàfikún ọ̀rọ̀ rẹ̀ wípé, àgbékalè àti ohun tí àwọn ènìyàn ọ̀hún gẹ́gẹ́bí ẹgbẹ́ alátìlẹ́yìn lẹka kan nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC gan an ò jẹ́ ojúlówó nítorí wọn ò ṣèforúkọsílẹ̀ wọn leyi tó túnmọ̀ sí pé, ẹgbẹ́ ò ṣèdámọ̀ wọn.
Ó ní èyí tí ó pani ní ẹ̀rín jùlọ ni èrò àwọn ènìyàn náà láti ṣàtakò si ìṣàkóso Ààrẹ Muhammad Buhari nínú ẹgbẹ́ òṣèlú náà àtipé bíbu ẹnu àtẹ́ lù ú ti múwọn ṣẹ̀sí ẹ̀sùn ìdúnkookò mọ́ ìjọba.
Ó tẹ̀ síwájú wípé dandan ni báyìí fún àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò gbogbo láti rí sí ìwà kòtọ́ tí àwọn ènìyàn yí hu, àtipé gbogbo ìgbésẹ̀ ẹ kárími tí wọn ń gbé nínú ẹgbẹ́ òṣèlú náà ò níí jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà.
O tún ṣe é lálàyé wípé, ìmọ̀ràn tí àwọn lè gba àwọn aráàlú ni wípé, kí wọn ó má kàwọ́nsí ǹkankan rárá nítorí wọn ò kí ń ṣe ojúlówó ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC àtipé àwọn ẹgbẹ́ alátakò kan ló ń lòwọ́n láti máa fi dabarú ohunkóhun tí àwọn bá ń ṣe.
Ó tún ní, àṣeyọrí ìpàdé tí àwọn adarí ẹgbẹ́ òṣèlú APC, àti ìgbìmọ̀ àwọn gómìnà lẹgbẹ òṣèlú APC ṣe pẹ̀lú Ààrẹ Muhammad Buhari, ló bí ìfẹnukòlé Oṣù Kejì Odun 2022 gẹ́gẹ́bí ọjọ́ ìpàgọ́ ńlá gbogbogbò ẹgbẹ́ òṣèlú náà.
Àmọ́ lọ́wọ́ báyìí o, Wọ́n ní wámú-wámú bayi ni àwọn òṣìṣẹ́ ẹ̀ṣọ́ aláàbò dúró sí ilé ẹgbẹ́ òṣèlú náà nítorí àhesọ tó ń lọ wípé àwọn kan ti ń dìmọ̀lù láti gbàjọba lọ́wọ́ àwọn ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣẹ́ ẹgbẹ́ náà.
Share this page with your family and friends.