-
1K Views
0 Comments
3 Likes
0 Reviews
Kàyééfì!
Ìròyìn tó gbalé, gbalẹ̀ kankan lọ́jọ́ ẹtì to kọjá yí lórí ẹ̀rọ ayélujára nípa ti ìṣẹ̀lẹ̀ tí wọn ló ṣẹ̀ n'ilu Ibadan Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ nibiti wọ́n ní àwọn agbéni ṣòògùn owó ti sọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ Bashorun High School di iṣu ló mú kí Kọmíṣọ́nà ètò ẹ̀kọ́ nipinlẹ náà arákùnrin Abíọ́dún Abdul Rahman sọ̀rọ̀ wípé kò sì òtítọ́ kankan nínú ìròyìn náà.
Gẹ́gẹ́bí ohun tí ìròyìn fi lélẹ̀ lọ́jọ́ ẹtì tó kọjá, wọ́n ní àwọn agbéni ṣòògùn owo ní wón sọ awon akẹ́kọ̀ọ́ mélòó kan diṣu lágbègbè Bode-Wasinmi, Bashorun n'ilu Ibadan to sì jẹ́ pé ọwọ́ àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò padà tẹ̀wọ́n.
Àmọ́ Kọmíṣọ́nà ètò ẹ̀kọ́ nílẹ̀ náà ṣàlàyé wípé àhesọ ọ̀rọ̀ lásán ni ìròyìn ọ̀hún nítorí ìwádìí tí òun ṣe nílé ẹ̀kọ́ Bashorun High school lọ́dọ̀ àwọn aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ náà jẹ́ kí òun mọ̀ wípé kò sí ẹnì kankan nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nílé ẹ̀kọ́ náà tí wọ́n ṣàfilọ̀ rẹ wípé wọ́n ń wá.
Ó tẹ̀ síwájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ wípé lóòótọ́ ni ìwádìí ń lọ lábẹ́lẹ̀ lójúnà àtilè mọ èyí tójẹ́ òkoodoro. Ó ní ìṣàkóso gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde gan an ò ní fààyè gba irúfẹ́ ìwàkíwà bẹ́ẹ̀ lábẹ́ẹ bí í tí wulẹ̀ ọ́ mọ.
Share this page with your family and friends.