-
1.4K Views
0 Comments
0 Likes
0 Reviews
Ìwà ọmọlúwàbí jẹ́ ìwà kan pàtàkì tí ènìyàn gbọ́dọ̀ ní lọ́wọ́, nítorí lọ́pọ̀lọpọ̀ ìgbà ó máa ń sábà á ṣílẹ̀kùn oore àti ìrànwọ́ àìlérò fúnni. Àtipé ó dàbí òògùn ẹ̀yọ́nú nítorí pé, ọ̀pọ̀ ènìyàn ni ó máa ń fẹ́ bá ọmọlúwàbí ènìyàn ṣe.
Irúfẹ́ ìwà ọmọlúwàbí yi ni arábìnrin oníṣòwò kárà-kátà kan hù láìpẹ́ yi nígbà tó dá àpamọ́ oníbara rẹ padà fún un lẹ́yìn oṣù mẹ́ta tí ìyẹn ti gbàgbé rẹ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀.
Gẹ́gẹ́bí ìròyìn ti fìdí rẹ múlẹ̀, oṣù mẹ́ta sẹ́yìn ní arábìnrin kan tí wón ń pè ní Màmá Funmkẹ lọ rajà lọdọ obìnrin yí. Lẹ́yìn tí ó ti lọ tán, ni obìnrin òǹtajà yí kíyèsí àpamọ́ onibara rẹ tó ń jẹ́ Màmá Funmkẹ. Kò sì mọlé-mọ̀nà rẹ̀, èyí ló fàá tó fi pinnu láti báà tọ́jú rẹ̀ dìgbà míràn tí ó bá tún padà wá sọ́jà. Àpamọ́ yi ní owó àti ọ̀pọ̀ ǹkan oníyebíye nínú o.
Èrò arábìnrin òǹtajà yí ni wípé, onibara òun ò ní pẹ́ẹ́ wá bèèrè fún àpamọ́ rẹ tí ó gbàgbé sọ́dọ̀ rẹ, àmọ́ bẹ́ẹ̀ kọ́ lọ̀rọ̀ rí nítorí Màmá Funmkẹ ò désọ̀ obìnrin náà àyàfi lẹ́yìn oṣù kẹta.
Lọ́jọ́rú ọjọ́ kẹjọ oṣù Kejìlá yí, ní arábìnrin òǹtajà yí rí Màmá Funmkẹ ní ìsọ̀ rẹ tówá rajà lọ́wọ́ rẹ, kódà kò mẹ́nu lọ ibi ọ̀rọ̀ àpamọ́ rẹ tówà lọ́wọ́ ẹni tí ń tajà fún un. Èyí ló mú kí arábìnrin òǹtajà náà ó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ wípé ǹjẹ́ ó tilẹ̀ sọ àpamọ́ rẹ nù ní ǹkan bí i oṣù mẹ́ta sẹ́yìn, arábìnrin yi sì ní bẹ́ẹ̀ni. Láìsọsẹ̀, arábìnrin òǹtajà yí mú àpamọ́ náà jáde. Ó ti bu, ìdọ̀tí ti wà ní gbogbo araarẹ̀, kódà àwọn owó tó wà nínú rẹ ti n runlé, bẹ́ẹ̀ wón ti ń bu díẹ̀díẹ̀.
Sí ìyàlẹ́nu Màmá Funmkẹ tó ni àpamọ́ yí, digbí ni gbogbo owó àti nkan miran tówà nínú àpamọ́ náà wà. Èyí sì jẹ́ ohun ìwúrí ńlá gbáà fún un. Kò ṣègbè rárá láti fi ìwà ọmọlúwàbí arábìnrin náà tó àwọn èèyàn létí nítorí ó ń yà á lẹ́nu wípé irúfẹ́ àwọn èèyàn bíi arábìnrin yi ṣì wà.
Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé, bí ènìyàn bá ń gúnyán bọ́ ìlú yóò lọta, èyí gan an ló fẹ́rẹ̀ ṣẹ mọ́ arábìnrin onínú ire yi lára nítorí àwọn kan tí wọ́n gbọ́ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà sọ wípé arábìnrin yí kì bá tíí fi àpamọ́ náà sílẹ̀ kábání owó tó wà nínú rẹ pọ̀ gan-an ni.
Àmọ́ tòhun tí bẹ́ẹ̀ náà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀dá ló gbé oríyìn ńlá fún arábìnrin òǹtajà yí nítorí ó sọ wípé àìmọ̀ ilé tàbí mọ ibití òun lè wá oníbara oun sí ni, bí bẹ́ẹ̀kọ́, òun ò bá ti dáa padà fún un tipẹ́ síwájú ọjọ́ náà.
Nítorí náà ẹyin alárá wa, ìwà ọmọlúwàbí ṣe pàtàkì púpọ̀, kí Olódùmarè ó máa fún gbogbo wa ṣe.
Share this page with your family and friends.