-
1.5K Views
0 Comments
0 Likes
0 Reviews
Ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ni arákùnrin yí. Abdul Azeez Ibrahim lórúkọ rẹ. Òun lẹni afurasí tí àwọn Ọlọpa ilẹ̀ wa ti olú ilé iṣẹ́ Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun n'ilu Ọ̀ṣogbo fojú rẹ̀ hàn lópin ọ̀sẹ̀ yí látàrí ẹ̀sùn tí wọn fi kàn án tó ní í ṣe pẹ̀lú ìwà jìbìtì.
Arákùnrin yí ni ìròyìn sọ nípa rẹ̀ wípé ó kúrò ní ìlú Ìwó lọsí Òṣogbo láti lọ ra ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan. Alùpùpù rẹ̀ ló gùn lọ. O ṣàlàyé ọ̀rọ̀ fáwọn Ọlọpa wípé
"Mo ní alùpùpù àti ọkọ Mazda kan. Àmọ́ ó wùnmí láti pààrọ̀ ọkọ̀ náà. Èyí ló múmi pinnu láti gba ìlú Òṣogbo lọ lójúnà àti ra ọkọ̀ míràn.
Mo dé ọ̀dọ̀ àwọn tí wọ́n ń ta ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, mo sì rí èyí tó wùnmí tí í ṣe Toyota Camry. A dúnàdúrà lórí rẹ, a sì fohùnṣọ̀kan lórí i mílíọ̀nù méjì ó lé ẹgbẹ̀rún lẹ́gbẹ̀ta àti àádọ́ta náírà. (N2, 650,000) àmọ́ mo ṣe ìfowóráńṣẹ́ sínú àpò àṣùwọ̀n àwọn tí mo fẹ́ ra ọkọ̀ náà lọ́wọ́ wọn. Iye tí mo sì taari síbẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ẹgbẹ̀ta lé laadota náírà (2,650).
Láìfura arákùnrin náà tó ta ọkọ̀ náà fúnmi, ó yàǹda gbogbo ìwé ọkọ̀ náà fúnmi mo sì wàá kúrò níbẹ̀ lọ sí Iwó. Lẹ́yìn náà ni mo ṣẹ̀ṣẹ̀ padà lọ gbé alùpùpù mi.
"Mi ò kúkú lo òògùn abẹnugọ̀ǹgọ̀ fún arákùnrin tí mo ra ọkọ̀ yí lọ́wọ́ ẹ̀, mo kàn rí i bí oríire mi ni. Ọkàn kan ló kàn ní kí n fi iye owó yẹn ráńṣẹ́ sínú àkáǹtì rẹ̀ tó fi di pé ó gbé ọkọ̀ náà kalẹ̀ fúnmi.
Mi ò jáfara rárá láti gbeelọ sọ́dọ̀ àwọn tí ń kun ọkọ̀ ni Ìwó láti bámi pààrọ̀ ọ̀ọ̀dà tíḿbẹ lára rè tẹ́lẹ̀ sí òmíràn lẹ́yìn iṣẹ́ àtúnṣe ráńpẹ́ lára rẹ̀. Àmọ́ ọwọ́ àwọn Ọlọpa tẹ̀mí ṣíwájú kí wọ́n ó tó kù ún tán.
Ẹni tí ó jẹ́ Kọmíṣọ́nà Ọlọpa ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun Olawale Olokode, ṣàlàyé ọ̀rọ̀ nigbati ó ń bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ wípé, lọ́gán ní àwọn agbófinró jígìrì sí ọ̀rọ̀ náà nigbati wọn ti ṣe àfinsùn ìṣẹ̀lẹ̀ náà latẹnu arákùnrin Kazeem Ogunjobi tó ta ọkọ̀ náà. O ni àwọn olopa sì bẹ̀rẹ̀ ìṣẹ́ ìwádìí títí tí wọn fi rí ọkọ̀ náà gbà padà kúrò lọ́wọ́ òṣìṣẹ́ atánkọ̀kùn tí afurasí náà gbéṣẹ́ fún.
Ọlọkọde ṣàlàyé wípé òṣìṣẹ́ atánkọ̀kùn náà tórúkọ rẹ ń jẹ́ Olayinka Bashiru ti fẹ́rẹ̀ parí kíkùn ọkọ̀ náà nípa pípààrọ̀ ọ̀ọ̀dà ara rẹ láti ààwọ̀ ewé sí ààwọ̀ wúrà gẹ́gẹ́ bíi àlàálẹ̀ ẹni afurasí ọ̀hún. Kọmíṣọ́nà olopa tún wáá ṣàlàyé wípé wọ́n máa gbé arákùnrin náà relé ẹjọ́ ní kété tí ìwádìí báti parí l'ori rẹ̀.
Share this page with your family and friends.