-
1.5K Views
0 Comments
1 Like
0 Reviews
Látàrí ìwà kòtọ́ tí arákùnrin ẹni ọdún mẹ́rìnlélógójì Onyekwere Ezewonye hù sí àbúrò rẹ obìnrin kan nípa lílùú bíi kíkú bíi yíyè nítorí ogún ló mú délé ẹjọ́ láìpẹ́ yi nílùú Èkó.
Arákùnrin ẹni afẹ̀sùnkàn náà ni wọ́n gbé wá sílé ẹjọ́ Májísíréètì kan lágbègbè Ọ̀jọ́ lórí ẹ̀sùn méjì tónííṣe pẹ̀lú u títàbùkù ẹni àti bíba dúkìá jẹ́ lọ́nà tí kò bá òfin mú.
Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé o gbìyànjú àti ro àròjàre wípé òun ò jẹ̀bi ẹ̀sùn náà níwájú adájọ́ Májísíréètì náà Ademola Adesanya, àmọ́ Olùpẹ̀jọ́ ASP Simeon Uche, sọ fún ilé ẹjọ́ náà wípé arákùnrin yí hùwà kòtọ́ ọ̀hún lọ́jọ́ kẹẹ̀sán oṣù Kejìlá ọdún yi ni kìlómítà kẹtàlélógún, ojúnà Marose Èkó sí Badagry.
Olùpẹ̀jọ́ ọ̀hún ṣàlàyé pé, olùjẹ́jọ̀ náà lu ìbátan rẹ̀ Happiness Igwe látàrí gbọ́nmisi omi ò mí too tó ṣẹlẹ̀ láàárín wọn nítorí ọ̀rọ̀ ogún mọ̀lẹ́bí wọn kan tí wọ́n tà.
Gẹ́gẹ́bí àlàyé Olùpẹ̀jọ́, o ni arákùnrin olùjẹ́jọ̀ yí hùwà ìfàbùkùkanni sí Happiness Igwe tí ó jé ìbátan rẹ nítorí ìyẹn yẹ̀ẹ́ lọ́wọ́ wò lórí dúkìá náà tí ó tà. Kódà, wọ́n ní lọ́jọ́ yí kan náà ni ó tú mọ̀ọ́mọ̀ ba òrùlé ilé arábìnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Stella Eze jẹ́.
Olùpẹ̀jọ́ Uche wáá fìdí ọ̀rọ̀ lélẹ̀ wípé, ìwà tí arákùnrin olùjẹ́jọ̀ yí hù tako òfin ilẹ̀ wa ti èka 168 àti 350 ìwé òfin ìwà ọ̀daràn ti Ìpínlẹ̀ Èkó ọdún 2015.
Àbálọ-àbábọ̀ ọ̀rọ̀, ilé ẹjọ́ náà gba onídùúró rẹ pẹlu owó tííṣe ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọrun kan owó ilẹ̀ wá. Àti àwọn ènìyàn méjì miran ní iye kan náà.