-
1.4K Views
0 Comments
1 Like
0 Reviews
Mike Ozekhome to jẹ agbẹjọrọ fun Nnamdi Kanu to jẹ adari ikọ Biafra ti kọ we ranṣẹ si aarẹ Buhari lati fi Kanu silẹ ni panpẹ ni kiakia.
Ninu iwe ipẹjọ̀ to fi lede ni agbẹjọrọ naa ti ni ki Aarẹ Buhari paṣẹ fun adari eto idajọ ni Naijiria lati lo aṣẹ rẹ, ‘’Nolle Prosequi’’ labẹ ofin ọdun 1999, ki wọn fi jọwọ Kanu ko lọ ni alaafia.
Gẹgẹ bi ọrọ rẹ, o kesi aarẹ Buhari pe igbesẹ naa yoo jẹ ọna abayọ si bi wọn ṣe ti Kanu mọ inu atimọle, laibikita ilera ara rẹ, ati iru agbegbe ti wọn fi pamọ si.
Agbẹjọro rẹ to sọ bi iṣẹlẹ ṣe bẹrẹ ni Kanu n jẹ ẹjọ lọwọ ni ileẹjọ giga ni Naijiria, nigba naa lọhun, ti wọn si gba beeli rẹ, amọ awọn ikọ ọmọogun ilẹ Naijiria ṣe ikọlu si ile rẹ, to si mu sa asala fun ẹmi rẹ.
‘’Igbeṣẹ awọn ọmọogun naa fihan pe ijọba fẹ pa Kanu, eyi to si mu ki o gbera lọ si ilu London lati lọ ṣe atipo nibẹ.’’
''Lati ibẹ lo ti lọ si Kenya, ki awọn ikọ ọtẹlẹmuyẹ Naijiria pẹlu ajọṣe ilẹ Kenya fi panpẹ mu ni jọ Kẹrindinlọgbọn, Oṣu Kẹjọ, ọdun 2021, ti wọn si jigbe pẹlu ijiya fun ọjọ mẹjọ, ki wọn to gbe wa si Naijiria.’’
''Eleyii tapa si eto idajọ ni Naijiria, Kenya ati Ilẹ Gẹẹsi ti awọn itapa si ofin yii ti waye.''
‘’Ni Kenya ni wọn ti fi iya jẹ Kanu, ti wọn ko si mọ ibi to wa fun odindi ọjọ mẹjọ pẹlu ajọṣepọ laarin ẹka eto aabo ni Naijiria ati Kenya.''
Ozekhome wa rọ ijọba Naijiria lati tu silẹ ni igbekun nitori o tapa si ẹtọ rẹ gẹgẹ bi ẹniyan.
Bakan naa ni agbẹjoro naa ni orilẹede Kenya kọ lati sọ ti ẹnu wọn lori ipa ti wọn ko lati gbe Kanu wa si Naijiria.
Share this page with your family and friends.