-
2.2K Views
0 Comments
1 Like
0 Reviews
Orilẹ-ede North Korea ti yin ado oloro misaili kan, eyii to fo gba orilẹ-ede Japan kọja.
Awọn onimọ nipa ohun to n lọ kakiri agbaye sọ pe igbesẹ naa jẹ ọna lati mọọmọ tọ ija orilẹ-ede Japan ati Amẹrika ni.
Misaili naa lo fo fun nnkan bii ẹgbẹrun mẹrin abọ kilomita ko to lọ ja sinu agbami okun Pacific Ocean.
Igba akọkọ ree ti misaili North Korea yoo fo gba orilẹ-ede Japan kọja lati ọdun 2017.
Lasiko ti misaili naa n fo, ijọba Japan kede fun awọn ọmọ orilẹ-ede rẹ lati lọ wa ibi ti wọn yoo fara pamọ si nitori wọn ko mọ ibi ti ado oloro naa le balẹ si.
Ṣaaju ni ajọ iṣọkan agbaye, UN, ti kọkọ fofin de North Korea pe ko gbọdọ gbọ iṣẹ ohun ija oloro bii ti misaili naa wo.
Ọpọ orilẹ-ede to ni ohun ija oloro bẹẹ ni ki n gbọ iṣẹ rẹ wo nitori awọn orilẹ-ede to yi wọn ka le ri bi igba ti wọn ba n kọju ogun si wọn.
Ọpọ eeyan ni Ariwa Japan bii Kokkaido ati Aomori ni wọn gbọ iro misaili naa bo ṣe n fo kọja.
Bẹẹ ni wọn n gba oniruru atẹjiṣẹ pe ki wọn lọ wa ibi sa pamọ si tabi ki wọn maa lọ si aja ilẹ fun abo ara wọn.
Ọkan lara awọn olugbe Aomoro, Kazuko Ebina sọ fun ileeṣẹ iroyin Asahi Shimbun pe ẹru ba oun gidi nitori ibi ti ado oloro le balẹ si.
O ni “Ẹru bami, nitori ti misaili naa ba fi le balẹ, rogbodiyan nla ni yoo jẹ fun orilẹ-ede wa.”
Lẹyinorẹyin, ijọba ilẹ naa ni inu agbami okun Pacific Ocean ni ado oloro naa balẹ si, eyii to jina rere si Japan, ẹnikẹni ko si farapa.
Ẹwẹ, Aarẹ North Korea, Kim Jong-un ti sọ pe, ẹru orilẹ-ede kankan ko ba oun ti ogun ba ṣẹlẹ, paapaa pẹlu Amẹrika, nitori ohun ija ogun wa nilẹ digbi.
Share this page with your family and friends.