-
1.4K Views
0 Comments
1 Like
0 Reviews
Igbimọ to n gbọ ẹhonu esi ibo gomina ti bẹrẹ ijoko nipinlẹ Ekiti.
Nibi ijoko naa to waye lọjọbọ ni awọn isẹlẹ kan ti waye eyi to mu ki ariwo sọ.
Segun Oni, tii se gomina ipinlẹ naa tẹlẹ ati oludije gomina fẹgbẹ oselu SDP to pe ẹjọ naa, lo awọn ẹri rẹ kan wa sile ẹjọ.
Awn ẹri naa lo fi n sọ awijare rẹ pe mọkaruru wa ninu esi ibo gomina naa, to gbe oludije fẹgbẹ oselu APC, Abiodun Oyebamji wọle.
Oni si ko iwe idibo to pọ ju ibudo idibo nipinlẹ Ekiti wa sile ẹjọ naa gẹgẹ bii ẹri, ti ọpọ eeyan to wa nibẹ si figbe ta.
Ṣaaju ni Oni ti kọkọ sọ pe ajọ eleto idibo, INEC ko fun oun laye lati ko awọn iwe ati irinṣẹ ti wọn lo lasiko eto idibo naa, bii ẹrọ BVAS, eyii ti oun fẹ ko wa siwaju igbimọ naa gẹgẹ bii ẹri.
Amọ Ọmọba Lateef Fagbemi, to jẹ agbẹjọro oludije fẹgbẹ oṣelu APC to jawe olubori, Biodun Oyebanji, sọ fun igbimọ naa, ko ma ṣe gba awọn ẹri ọhun wọle.
Nigba ti aago mejila ọsan kọja iṣẹju diẹ ni igbimọ naa lọ fun isinmi ranpẹ, titi di aago meji abọ ti wọn bẹrẹ si n fi ọrọ wa Segun Oni lẹnu wo lori ẹjọ to pe.
Amọ lasiko ti isinmi naa n lọ lọwọ, ni wọn bẹrẹ si n ṣayẹwo awọn iwe idibo to ko wa, ti wọn si ṣakiyesi pe iwe naa pọ ju iye ibudo idibo to wa l’Ekiti lọ.
Ọrọ naa fa oniruru ariyanjiyan nibi ijoko naa laarin awọn agbẹjọro olupejọ atawọn olujẹjọ lori ẹni to jẹbi.
Nigba to n sọrọ lori ariyanjiyan naa, alaga igbimọ to n gbọ ẹhonu ibo ọhun, Wilfred Kpochi ni, ṣe lawọn ni ki wọn yẹ iwe kọọkan wo, ni ibamu pẹlu agọ idibo kọọkan.
O ni ki wọn to ṣakiyesi pe iwe naa pọ ju iye agọ idibo to wa nipilẹ Ekiti, eyii ti apapọ rẹ jẹ ẹgbẹrun meji ati arundinlaadọtalenirinwo.
O ni “Iwe ti wọn ko wa pọ ju iye agọ idibo to wa lọ, idajọ wa yoo si da lori iye agọ idibo to wa.
A fẹ ki wọn yẹ awọn iwe naa wo daadaa... a fẹ ko jẹ iwe kan lati agọ idibo kan ni.”
Lẹyin atotonu awọn agbẹjọro to wa nikalẹ, igbimọ naa sun igbẹjọ ijoko igbimọ ọhun siwaju lati le fun Segun Oni laaye lati tun awọn iwe naa yẹwo.
Share this page with your family and friends.