Ilé ẹjọ́ Májísíréeti kan tó fìkalẹ̀ ságbègbè Ìkẹ̀jà ti gba onídùúró arákùnrin òṣìṣẹ́ báńkì ẹni ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n kan, Ridwan Adejoju lówó miliọọnu kan Náírà látàrí ẹ̀sùn ìwà jìbìtì tí wọ́n fi kàn án.
Arákùnrin ọ̀hún ni wón sọ wípé ó jí owó tótó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀ta pẹ̀lú ọgbọ́n àlùmọ̀mọ́kọ́yí lọ́wọ́ arákùnrin kan tí wọ́n pè ní Bóyèjọ Ògúnbánjọ nípa wípé òun o baa gba ìwé àṣẹ ilé kíkọ́ C of O ni Alausa, Ìpínlẹ̀ Èkó.
Ìwádìí sọ wípé gbogbo ọ̀nà ni arákùnrin yí kọ́kọ́ gbà láti fi ète gba owó náà àmọ́ pàbó ló já sí, tósìjẹ́pé lẹ́yìn náà lo ṣẹ̀ṣẹ̀ wáá jíi mọ́ arákùnrin tólowó náà lọ́wọ́.
Àmọ́ adájọ́ Májísíréeti Elizabeth Adeola ti ní kí wọ́n gba onídùúró arákùnrin náà pẹ̀lú mílíọ̀nù kan náírà lẹ́yìn Ìgbà tí ó loun o jẹ̀bi ẹ̀sùn ọ̀hún.
Adájọ́ náà wáá ṣe é lálàyé wípé ó gbọ́dọ̀ ní onídùúró méjì tí ó jé òṣìṣẹ́ ìjọba tí ó sì ń san owó orí rè déédéé niyekanna tí ẹni afẹ̀sùnkàn yóò sàn.
Lẹ́yìn èyí ni wón sún ìgbẹ́jọ́ sí ọjọ́ kẹẹdogun oṣù Kejìlá ọdún yí.
Share this page with your family and friends.