KÀYÉÉFÌ, ỌKÙNRIN KAN LU ỌMỌ OṢÙ MÉJÌ PA N'ILU ÒṢOGBO. Ọwọ́ àwọn agbófinró ti tẹ arákùnrin ẹni ọdún mẹ́tàlélógójì(43) kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sanjọ́ n'ilu Òṣogbo. Ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn arákùnrin ọ̀ún ni wípé ó lu ọmọ bíbí inú rẹ̀ ọmọ oṣù méjì lálùpa lágbègbè Alékúnwodò, Òṣogbo.
Arákùnrin náà gbìyànjú àròjàre wípé òun ò mọ ohun tí ó bà lé òun rárá nítorí òun gbìyànjú láti rọ ọmọ náà kí ó dákẹ́ ẹkún ni nígbà tí ìyá rẹ̀ kò sí nílé. Ó ní gbogbo ọ̀nà lòun gbà láti rẹ ọmọ náà lẹ́kún àmọ́ tí kò ṣe é ṣe tó fi wáá jẹ́ pé òun padà lùú pa.
Àwọn ará àdúgbò tí wọn kẹ́ẹ́fín ìṣẹ̀lẹ̀ yí níwọ̀n yára fi tó àwọn agbófinró létí nítorí wọ́n ní tọkọtaya fẹ́ẹ́ fi ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe òkú òru ni. Àmọ́ nígbà tí wọ́n wadi lẹ́nu arábìnrin ìyá ọmọ náà kí nìdí tí ó fi rí bẹ́ẹ̀, àlàyé tí ó ṣe ni wípé ọmọ márùn-ún ni àwọn bí lápapọ̀, àmọ́ látàrí ìyà, ìṣẹ́ àti òṣì tó ń bá àwọn fínra ló mú kí àwọn ó fúnra àwọn pa méjì nínú àwọn ọmọ náà nígbà kan.
Àmọ́, ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀rọ̀ burúkú yí lo mú wọn dé ọ̀dọ̀ àjọ tó ń rí sí ìtẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lójú mọ́lẹ̀ àti ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀dọ́ àti obìnrin n'ilu Òṣogbo níbi tí ìwádìí tí ń lọ lọ́wọ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Comments