Láìpẹ́ yí ni ìròyìn kan gbàgboro kan wípé wọ́n jí òǹdíjedupò gómìnà ní Ìpínlẹ̀ Imo lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú Action Alliance (AA) Olóyè Uche Nwosu lọ́dún 2019 gbé nílé ìjọsìn kan lọ́jọ́ àìkú tó kọjá yí, àmọ́ tó jẹ́ pé àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹtẹ̀múyẹ́ ilẹ̀ẹwa tètè yára tako ìròyìn náà wípé ...
Èròńgbà gbogbo ènìyàn lásìkò ọdún kọ̀ọ̀kan ni pé, bí ọdún bá ti ń lọ sópin bí èyí kí Olódùmarè o máa fìṣọ́ rẹ̀ ṣọ́ni nítorí àtilè rọ́dún tuntun. Ọ̀pọ̀ ló sì tún máa ń wùn láti rìnrìn àjò lọ sí ìlú wọn lójúnà àtirí àwọn mọ̀lẹ́bí wọn tí wọ́n ti rí tipẹ́ pàápàá àwọn ènìyàn gbogbo tó...
Látàrí erongba Ìjọba àpapọ̀ ilẹ̀ yí láti rí i wípé ìgbáyé gbádùn àwọn aráàlú jẹ́ ohun ojúṣe ìjọba pàápàá lásìkò ọdún Kérésìmesì àti ọdún tuntun tó ń bọ̀ lọ́nà, ló mú kí wọn o kéde rẹ̀ wípé àǹfààní yóò wà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ arìnrìn-àjò láti ṣàmúlò ọkọ̀ ojú irin tí wọ́n gbé kalẹ̀ lásì...
Látàrí ojú ìwòye tí gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní Ìpínlẹ̀ Imo Rochas Okorocha fi ń wo bí ohun gbogbo tí ń lọ nílẹ̀ yí, pàápàá ìrúnú àwọn ọ̀dọ́ nípa ìṣàkóso ìjọba orílẹ̀ èdè yí, ló mú u tètè ké sí àwọn ọ̀dọ́ orílẹ̀-èdè yí pẹ̀lú ẹkún wípé kí wọn ó má fi ìkanra mọ́ àwọn aláìṣẹ̀ gbogbo bíi àwọ...
ILÉEṢÉ ỌMỌ OGUN ILẸ̀ẸWA Ò FÌYÀ JẸ ỌMỌBÌNRIN NÁÀ RÁRÁ O, A KÀN FI PAMỌ́ SÍ YÀRÁ ÀWỌN ALÁÌGBỌRÀN NI. Látàrí awuyewuye kan tó ń lọ lọ́wọ́ lórí ẹ̀rọ ayélujára lákòókò yí nípa pé àwọn ológun ilẹ̀ yí ti ń fìyà pá ọmọbìnrin ọmọ ogun ilẹ̀ẹwa kan tí fọ́nrán amóhùnmáwòrán rẹ̀ gba orí ẹ̀rọ ...
Ọ̀kan nínú àwọn ondije dupò Ààrẹ ọdún 2019 nínú ètò ìdìbò gbogbogbò tó kọjá Comrade Ademola Babatunde Abidemi Samuel ti bu ẹnu àtẹ́ lu ọ̀pọ̀ ọmọ orile-ede Naijiria tó ń ro ikú ro Ààrẹ Muhammad Buhari. Arákùnrin yi ṣe é lálàyé wípé òun lè fi irúfé àwọn ẹ̀dá bẹ́ẹ̀ wé àwọn janduku a...
Látàrí ìwà kòtọ́ tí arákùnrin ẹni ọdún mẹ́rìnlélógójì Onyekwere Ezewonye hù sí àbúrò rẹ obìnrin kan nípa lílùú bíi kíkú bíi yíyè nítorí ogún ló mú délé ẹjọ́ láìpẹ́ yi nílùú Èkó. Arákùnrin ẹni afẹ̀sùnkàn náà ni wọ́n gbé wá sílé ẹjọ́ Májísíréètì kan lágbègbè Ọ̀jọ́ lórí ẹ̀sùn méjì ...
Iléeṣé Ọlọ́pàá ẹ̀ka ti Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ti fọwọ́ ṣìkún òfin mú ọ̀kan láraawọn, Sájẹ́ńtì Ọnatunde Jọba tí fọ́nrán amóhùnmáwòrán rẹ̀ tàn kán orí ẹ̀rọ ayélujára láìpẹ́ yí tó ṣàfihàn rẹ̀ gẹ́gẹ́bí ẹni tó ti mutíyó tí ó sì ń ṣe kántan-kàntan kiri. Alukoro Ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun SP Yemisi ...
Púpọ̀ nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń ṣẹlẹ̀ lákòókò taawayi ló ń jẹ́ ohun ìkọminú fún ni wípé níbo gan-an la fẹ́ẹ́ bá yàrá já nípa ìwà búburú àwọn ọmọ ènìyàn. Nítorí pé lọ́pọ̀lọpọ̀ ìgbà tí a bá gbọ́ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ míràn, èèyàn ó sì maa ròó wípé àbíléayé yí kọ́ lati ń gbé tẹ́lẹ̀ ni. Ìdí àsa...
Ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ni arákùnrin yí. Abdul Azeez Ibrahim lórúkọ rẹ. Òun lẹni afurasí tí àwọn Ọlọpa ilẹ̀ wa ti olú ilé iṣẹ́ Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun n'ilu Ọ̀ṣogbo fojú rẹ̀ hàn lópin ọ̀sẹ̀ yí látàrí ẹ̀sùn tí wọn fi kàn án tó ní í ṣe pẹ̀lú ìwà jìbìtì. Arákùnrin yí ni ìròyìn sọ nípa rẹ̀...
Share this page with your family and friends.