A O NÍÍ ṢALÁÌ FỌWỌ́ ṢÌKÚN ÒFIN MÚ ẸNIKẸ́NI TÓBÁ TÀPÁ S'ÓFIN TÓRỌ̀MỌ́ ÌRÌNÀJÒ SÓKÈ ÒKUN LÓRÍ Ọ̀RỌ̀ ÀJÀKÁLẸ̀ ÀRÙN COVID-19 TUNTUN, OMICRON.
-ÌJỌBA ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ LÓ WÍ BẸ́Ẹ̀.

. . Ìwé ìrìnnà irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ máa d'ohun àgbẹ́sẹ̀lé f'ọ̀dún kan.
…Ìkìlọ̀ gómìnà rèé fún ẹni tó bá gba ayédèrú ìwé ẹ̀rí àbájáde àyẹ̀wò COVID-19
Gomina Ìpínlẹ̀ Èkó, Arákùnrin Babájídé Sanwo-Olu lo sọ̀rọ̀ yí lọ́jọ́ ìṣẹ́gun tó kọjá yí wípé ìṣàkóso òun ò ní ṣaláì ṣẹjọ́ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni tí aje ìwà àìgbọ́ràn nípa àlàálẹ̀ ìrìn àjò sókè òkun bá ṣímọ́ lórí, látàrí bí àwọn ìgbìmọ̀ iléeṣẹ́ ààrẹ ti ṣàgbékalẹ̀ rẹ̀.
Gómìnà Sanwo-Olu ṣàlàyé wípé ifowosowopo ìjọba Ìpínlẹ̀ Èkó àti àwọn ìgbìmọ̀ iléeṣẹ́ ààrẹ ti ṣetán láti gbé ẹnikẹ́ni tó bá kùnà láti jọ̀wọ́ araarẹ̀ fún àyẹ̀wò àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19 tuntun, omicron nítorí pé ó pọndandan. Àtipé irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ máa dáraalẹ̀ lẹbi nítorí pé ọdún kan ni wón máa fi gbẹ́sẹ̀ lé ìwé ìrìnnà rẹ àtipé orúkọ rẹ̀ máa wà lára àkọọ́lẹ̀ àwọn aláìgbọràn ẹ̀dá.
Gomina tẹ̀síwájú wípé, ó pọndandan fún gbogbo ààrè tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ dé sínú ìlú yí láti lọ fún àyẹ̀wò ara ẹnì láwọn ibùdó àyẹ̀wò aladani gbogbo tó wà káàkiri Ìpínlẹ̀ Èkó lákòókò tí ó yẹ fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí kíkùnà láti tẹ̀lé àlàálẹ̀ yí lè mú kí wọn ó fi irúfẹ́ ààrè bẹ sòkò padà sí ìlú rẹ̀ tótiwá.
Lára àlàálẹ̀ tuntun tí àwọn ìgbìmọ̀ iléeṣẹ́ ààrẹ lórí ọ̀rọ̀ àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19 tuntun omicron tuntun ọ̀hún ṣàgbékalẹ̀ rẹ nipé, ó pọndandan fún gbogbo arìnrìn-àjò tó bá fẹ́ẹ́ dé sórílẹ́èdè yí láti ṣe àyẹ̀wò kan tíwọ́n ń pè ní PCR láàrin wákàtí mejidinlaadọta tí wọ́n máa dé sí orílẹ̀ èdè yí, àyẹ̀wò míràn tún ni àyẹ̀wò tí wọn o ṣe lẹ́yìn ọjọ́ kejì tí wọ́n wọ̀lú. Àtipé gbogbo àwọn tí wón ti gba abẹ́rẹ́ náà láàbọ̀ tàbí tí kò tíì gbàá rárá gbọdọ̀ yaraawọn sọ́tọ̀ fún ọjọ́ méje gbáko nígbà kigbà tí wọ́n bá wọ̀lú wá. Bẹ́ẹ̀ sì ni àbájáde àyẹ̀wò PCR yí ti gbọ́dọ̀ tẹ̀wọ́n lọ́wọ́ lọ́jọ́ keje ti wón ti dé.
Gbogbo arìnrìn-àjò tí ó básì fẹ́ẹ́ jáde kúrò n'ilu náà gbọ́dọ̀ fi ẹ̀rí àrídájú hàn wípé wón ti gba gbogbo abẹ́rẹ́ tí ó yẹ láti gbà tí yóò safihan wípé wón wẹ̀ yán kàìnkàìn lọ́wọ́ àjàkálẹ̀ àrùn ọ̀hún láàárín ọjọ́ méjì tó ṣíwájú ìgbà tí wón máa gbéra kúrò lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Gomina Sanwo-Olu fi ẹ̀rí àrídájú lélẹ̀ wípé pẹ̀lú ìnáwó ńlá gbáà ni ọ̀rọ̀ àjàkálẹ̀ àrùn ọ̀hún ń gbà, àti pé, ìlanilóòógùn rẹ ò kéré, àmọ́ ìṣàkóso ìjọba òun ò ní dáwọ́dúró láti sa gbogbo ipá rẹ láti dá ààbò bo ẹ̀mí àti ìgbé ayé àwọn ènìyàn gbogbo ní Ìpínlẹ̀ Èkó.
Ó tẹ̀síwájú wípé gbogbo ètò làwọn ti ń ṣe báyìí láti má lè jẹ́ kí ìbúrẹ́kẹ́ rẹ ó wà ní ìpele ẹlẹ́kẹ̀rin rẹ. Ó ní laipe, àwọn máa ṣí ibùdó àyẹ̀wò bí ọgbọ̀n.