Irawọ oṣere Nollywood nni, Damilọla Oni ti kọminu l'ori bi awọn ololufẹ iṣẹ rẹ l'ọkunrin (male fans) ṣe ma fi awọn fọnran ati aworan isẹkusẹ ti wọn ṣe l'asiko ti wọn ba n wo oṣere naa ranṣẹ si.
Oṣerebinrin a-ri-ma-le-e-lọ naa lo sọ eyi mọ ọrọ l'asiko to n ṣalaye iriri rẹ ni'di iṣẹ tiata ati ninu igbesiaye l'ori eto ifọrọwọrọ kan ni ile-iṣẹ amohunmaworan Oyinmọmọ TV l'oju opo YouTube.
Ninu ọrọ rẹ, o ni iwa palapala naa ti wa buru to bẹẹ gẹ to jẹ pe ni kutu-hai ni wọn a ti ma fi awọn fọnran ati aworan nnkan ọmọ ọkunrin ranṣẹ si oun l'aarin awọn oun miran.
Pataki l'ara ohun ti oṣere naa mẹnuba ni pe, lọpọ igba awọn to ba jẹ alapẹpẹ ni iṣẹ tiata ma n pe, di'po awọn to l'ẹbun to dantọ. Damilọla jẹ ko di mimọ pe ariwo ọja gan ni aye n jẹ, ti ẹbun nikan ko si to lati tayọ nidi iṣẹ ere.
Amọ ṣa, Damilọla Oni jẹ ko di mimọ pe oun ṣetan lati ṣiṣẹ tiata goke agba lai fi ti adojuko ṣe.
Share this page with your family and friends.