-
1.3K Views
0 Comments
0 Likes
0 Reviews
Púpọ̀ nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń ṣẹlẹ̀ lákòókò taawayi ló ń jẹ́ ohun ìkọminú fún ni wípé níbo gan-an la fẹ́ẹ́ bá yàrá já nípa ìwà búburú àwọn ọmọ ènìyàn. Nítorí pé lọ́pọ̀lọpọ̀ ìgbà tí a bá gbọ́ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ míràn, èèyàn ó sì maa ròó wípé àbíléayé yí kọ́ lati ń gbé tẹ́lẹ̀ ni.
Ìdí àsamọ̀ ọ̀rọ̀ yí ni pé, láìpẹ́ yí ni ọwọ́ àwọn Ọlọpa tẹ arákùnrin ẹni mẹ́rìndínlógùn kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Salawudeen Lukman n'ilu Òṣogbo látàrí ẹ̀sùn ìpànìyàn àti fífini ṣòògùn owó tí wọ́n fi kàn án. Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé, arákùnrin òun sẹ́ kanlẹ̀ wípé òun kì í báwọn pànìyàn bíkòṣe láti rànnìyàn lọ́wọ́ láti ṣòògùn owo.
Nígbà tí àwọn ọlọ́pàá ń fojú rẹ̀ léde fún àwọn ènìyàn ní olú iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun n'ilu Òṣogbo ni arákùnrin náà ti ṣàlàyé ọ̀rọ̀ kan wípé ẹnìkan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Alfa Semiu ló kó àwọn ẹ̀yà ara ènìyàn wá fún oun, èyí tí í ṣe Orí àti àtẹ́lọwọ́ láti fi bá a ṣòògùn owó.
Gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ rẹ, ó ní Fulani kan ló kọ́ òun ní àṣírí òògùn owó ṣíṣe náà àti pé òun ò gbìyànjú rẹ̀ wò rí níwọ̀n ìgbà tí òun ò rí ẹni tí òun máa ṣe é fún. Ó ní inú òun wáá dùn nígbà tí Alfa Semiu yí wáá bèèrè fún ún láti ṣe, lòun ṣe ni kí òun ó ti ẹ̀ dọ́gbọ́nẹ̀ wò níwọ̀n ìgbà tí ó bá ti rí àwọn èròjà rè.
O ni lẹ́yìn tí ó kó àwọn èròjà náà wá tán, lòun wáá ṣe ọṣẹ dúdú kan fún un láti máa fi wẹ̀ àmọ́ òun ò láǹfààní láti fi lée lọ́wọ́ kótóódipé ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá tẹ òun.
Ó ní: "Mi ò mọbi tí ó ti rí orí àti àtẹ́lọwọ́ ènìyàn tó kó wá, àmọ́ ó sọ fúnmi wípé ẹnìkan ló kóo foun n'ilu Ilé-ifẹ̀"
Nígbà tí Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ní Ìpínlẹ̀ Òṣun Olawale Olokode bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀, ó ṣàlàyé wípé, àwọn agbofinro rí òkú arábìnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bọ́lájí Akérélé níbi tí àwọn òṣìkà ẹ̀dá jùú sí lápá ibì kan ní Ilé-Ifẹ̀.
Ó ní lẹ́yìn ìwádìí niwọ́n tóómọ̀ wípé wọ́n ti gé orí àti àtẹ́lọwọ́ rẹ lọ,èyí tí ó mú kí àwọn Ọlọ́pàá ó tẹpẹlẹ mọ́ ìwádìí wọn leyi tó sì ṣokùnfà fífi ọwọ́ ṣìkún òfin mú arákùnrin kan tí wọn ń pè ní Sunday Olajide tí wọ́n fura sí wípé ó lẹ́bọ lẹ́rù lórí ikú arábìnrin ọ̀hún.
Ọjọ́ kẹfà oṣù Kejìlá ọdún yí ni wọn kọ́kọ́ mú Sunday Olajide yí, ipasẹ̀ rẹ̀ náà niwọ́n sì gbà mú àwọn afurasí mẹta miran nilu Ìwó, Ìpínlẹ̀ Òṣun. Gbogbo wọn náà ló sì jẹ́wọ́ wípé àwọn làwọ́n ṣekúpa arábìnrin òun nípa fífún un lọ́rùn pa lójúnà àtifi ṣòògùn owó.
Ìwádìí tún wáájẹ́ kó di mímọ̀ pé olùgbé Ilé-Ifẹ̀ gan-an ni arábìnrin Bọ́lájí Akérélé tí wọ́n ṣekúpa náà ń ṣe. Atipé wọn máa gbé àwọn ènìyàn náà relé ẹjọ́ ní kété tí ìwádìí báti parí lóríiwọn