Ọ̀kan nínú àwọn ondije dupò Ààrẹ ọdún 2019 nínú ètò ìdìbò gbogbogbò tó kọjá Comrade Ademola Babatunde Abidemi Samuel ti bu ẹnu àtẹ́ lu ọ̀pọ̀ ọmọ orile-ede Naijiria tó ń ro ikú ro Ààrẹ Muhammad Buhari. Arákùnrin yi ṣe é lálàyé wípé òun lè fi irúfé àwọn ẹ̀dá bẹ́ẹ̀ wé àwọn janduku adalaafia ilu láàmú tí wọ́n sì jẹ́ Ọ̀tà ìlọsíwájú orílè èdè wa.
Comrade Samuel, tí ó jẹ́ ondije dupò ààrẹ lábé àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú Nigeria Community Movement Party, NCMP,àmọ́ tó Pàdánù ipò náà sọ́wọ́ọ Ààrẹ Muhammad Buhari sọ wípé irú èrò báwọ̀nyí kò yẹ ká máa ròó sí ẹnikẹ́ni tí a bá pè ní olórí ìlú rárá. Ó sọ̀rọ̀ náà n'ilu Abuja laipe yí wipe a ní láti firú àwọn ẹ̀dá bẹ́ẹ̀ wé àwọn ẹgbẹ́ alákatakítà afẹ̀fíṣòfò Boko Haram, tàbí àwọn Ajínigbé àti jàǹdùkú adàlúrú.