bantaleyorubadunka December 24, 2021
3.3K views 0 Comments 1 Like 0 Reviews
Látàrí erongba Ìjọba àpapọ̀ ilẹ̀ yí láti rí i wípé ìgbáyé gbádùn àwọn aráàlú jẹ́ ohun ojúṣe ìjọba pàápàá lásìkò ọdún Kérésìmesì àti ọdún tuntun tó ń bọ̀ lọ́nà, ló mú kí wọn o kéde rẹ̀ wípé àǹfààní yóò wà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ arìnrìn-àjò láti ṣàmúlò ọkọ̀ ojú irin tí wọ́n gbé kalẹ̀ lásìkò ayẹyẹ ọdún yí.
Àtipé Ọ̀fẹ́ làwọn ènìyàn ó máa wọ ọkọ̀ ojú irin fún ìrìnàjò láti ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù Kejìlá ọdún yí sí ọjọ́ kẹrin oṣù kìíní ọdún 2022. Nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí ọ̀gá àgbà iléeṣé àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ọkọ̀ ojú irin nílẹ̀ yí, Fidet Okhiria bá àwọn àjọ tó ń k'óròyìn jọ n'ilu Abuja lọ́jọ́ Ẹtì ṣe, ló ti ṣe é lálàyé wípé ìpinnu ìjọba àpapọ̀ yí wà ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú iléeṣé ìjọba àpapọ̀ tó ń rí sí ìgbòkègbodò ìrìnnà ọkọ̀ láti lè mú ìgbáyé gbádùn bá àwọn ọmọ orile-ede Naijiria kí lílọ bíbọ̀ wọn ó le jẹ́ Ìrọ̀rùn lákòókò ọdún.
Arákùnrin yí tẹ̀síwájú wípé eléyìí máa jẹ́ kí lílọ bíbọ̀ àwọn arìnrìn-àjò ó jẹ́ Ìrọ̀rùn lákòókò ọdún. Bẹ́ẹ̀ ló tún ní ó pọn dandan fún gbogbo arìnrìn-àjò láti gba tíkẹ́ẹ́tì wọn láwọn ojúko tíjọba ti làkalẹ̀ láláì san owó kankan lójúnà àtilè fúnwọn láǹfààní àti rí ọkọ̀ náà wọ̀ láwọn ibi tí wọ́n fìdí wọn sọlẹ̀ sí. Bákan náà ni wọ́n tún gba gbogbo arìnrìn-àjò náà nímọ̀ràn wípé kí wọn o tẹ̀lé gbogbo àláálẹ̀ òfin COVID-19 nípa pé kí wọn ó wọ aṣọ ìbòjúbomú, kí wọn ó sì máa fọ ọwọ́ wọn loorekoore. Ó tún tẹpẹlẹ mọ́ọ wípé ojúṣe ìjọba àpapọ̀ ni láti rí i wípé ààbò àwọn arìnrìn-àjò ọkọ̀ ojú irin ọ̀hún jẹ ìjọba lógún púpò lákòókò lílọ bíbọ̀ wọn.
Afrosky, a vibrant social media platform dedicated to connecting people of African descent worldwide. We provide a space for users to share their experiences, connect with like-minded individuals, and celebrate African culture and heritage.
We strive to foster a supportive and inclusive community where users feel empowered to express themselves authentically.
Share this page with your family and friends.