Ẹ̀yìn Tinubu ni a tò sí, òun nìkan ló lè ṣé – Afenifere
Awọn agba ẹgbẹ Afẹnifẹre ti sọ pe awọn yoo ṣatilẹyin fun oludije sipo Aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, Asiwaju Bola Tinubu, lati di Aarẹ Nigeria.
Atilẹyin yi ni wọn ṣe ipinnu rẹ niluu Akure to jẹ olu ilu ipinlẹ Ondo lakoko ti wọn gbalejo Tinubu nile adari ẹgbẹ naa, alagba Reuben Fasoranti.
Gbajugbaja onkọwe to tun jẹ akọwe agba tẹlẹ ri fun ẹgbẹ Afẹnifẹre, Basorun Sehinde Arogbofa, lo gbẹnusọ fawọn adari ẹgbẹ naa nibi ipade ọhun.
Arogbofa sọ pe o di dandan ki awọn ṣatilẹyin fun Tinubu toripe o lagbara lati mu irẹpọ ba gbogbo ẹya to wa ni Naijiria, ti yoo si mu ilọsiwaju ba ilẹ yii.
Arogbofa ni Tinubu kii ṣe ọmọ Yoruba nikan, amọ o tun jẹ ojulowo ọmọ Nigeria.
O sọ fun Tinubu pe ko mojuto eto abo, ọrọ aje ati atunto iṣejọba to ba ti di Aarẹ Naijiria.
Onkọwe ọhun ni “Ko si eto aabo to peye fun wa mọ lorilẹ-ede yii, bẹẹ ni ọrọ aje ti dẹnu kọlẹ, a n fẹ ọlọpaa ipinlẹ lati le mu ki eto aabo o nipọn gidi”.
Ẹni to ti fi igba kan ri jẹ akọwe ijọba apapọ Naijiria ati oludije sipo aarẹ nigba kan ri, Oloye Olu Falae ninu ọrọ tirẹ sọ pe “Ti o ba ti di Aarẹ, dakun ṣiṣẹ lati tun orilẹ-ede yii ṣe.”
“A wa nibi lati fun ọ ni imọran to jọju toripe a ti dagba kọja ẹni ti ko ni iṣẹ kan lati ṣe, amojuto ọrọ aje ṣe koko toripe owo Naira ko niyi mọ, ko si ni pẹ di ẹgbẹrun kan Naira si owo dollar
kan.”
“A si ṣetan lati ti ọ lẹyin koo le yi eleyii pada. Oju wa ni yoo si ṣe nigba too ba gba ife ẹyẹ ipo Aarẹ pada wale”.
Igbakeji gomina ipinlẹ Oyo, Bayo Lawal, to ṣoju gomina rẹ nibi ijoko naa ni tirẹ ni gbogbo ohun to ba jẹ mọ idagbasoke ilẹ Yoruba lawọn maa n lọwọ si nipinlẹ wọn, o fikun pe awọn ko nii da duro yatọ sawọn ipinlẹ toku nilẹ Yoruba.
Tinubu ninu ọrọ rẹ dupẹ lọwọ awọn adari ẹgbẹ Afẹnifẹre, paapaa julọ Alagba Reuben Fasoranti fun atilẹyin rẹ to si wip e oun wa mu ẹjẹ oun ṣẹ lati pada wa ti oun ba gba ipo oludije lẹgbẹ oṣelu APC.
Oludije sipo Aarẹ naa waa rọ awọn adari Afẹnifẹre naa lati wa laaye titi ti oun yoo fi wọle bi Aare Naijiria lọdun to n bọ toripe oun yoo pada wa dupẹ lọwọ wọn lẹyin iburawọle.
Share this page with your family and friends.